Skip to content
Saamu 22:10-22

Saamu 22:10-22

10
Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá, nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.
11
Má ṣe jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.
12
Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13
Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù.
14
A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15
Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.
16
Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.
17
Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
18
Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.
19
Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi. Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20
Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21
Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.
22
Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi; nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options