Saamu 141:1-4
1
Saamu ti Dafidi. Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2
Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
3
Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa: kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
4
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi, láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
Settings