Saamu 119:81-88
81
Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82
Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84
Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85
Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86
Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé; ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87
Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88
Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
Settings