Saamu 119:89-96
89
Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
90
Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91
Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92
Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93
Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
94
Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95
Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96
Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
Settings