Òwe 6:26-35
26
Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan, ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.
27
Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná?
28
Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná? Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
29
Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.
30
Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
31
Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
32
Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni.
33
Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé.
34
Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
35
Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.
Settings