Òwe 29:1-7
1
Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
2
Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
3
Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.
4
Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
5
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
6
Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
7
Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.
Settings