Numeri 4:1-11
1
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
2
“Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
3
Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.
4
“Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ.
5
Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.
6
Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
7
“Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀.
8
Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
9
“Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.
10
Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.
11
“Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings