Numeri 3:1-19
1
Ìwọ̀nyí ni ìdílé Aaroni àti Mose ní ìgbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai.
2
Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari.
3
Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
4
Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn.
5
Olúwa sọ fún Mose pé,
6
“Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́.
7
Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní àgọ́ ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́.
8
Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.
9
Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.
10
Kí o sì yan Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”
11
Olúwa tún sọ fún Mose pé,
12
“Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi,
13
nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”
14
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose ní aginjù Sinai pé,
15
“Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè.”
16
Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.
17
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
18
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
19
Àwọn ìdílé Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
Settings