Numeri 23:18-26
18
Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ, “Dìde, Balaki; kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori.
19
Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
20
Èmi gba àṣẹ láti bùkún; Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.
21
“Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu, kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli. Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn. Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.
22
Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.
23
Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu, tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli. Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’
24
Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún; wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”
25
Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”
26
Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?”
Settings