Numeri 2:1-24
1
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
2
“Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”
3
Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
4
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).
5
Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Suari.
6
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400).
7
Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni.
8
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400).
9
Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ó lé irinwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.
10
Ní ìhà gúúsù: ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
11
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).
12
Ẹ̀yà Simeoni ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Simoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
13
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje (59,300).
14
Ẹ̀yà Gadi ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli.
15
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650).
16
Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́talélégbèje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.
17
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.
18
Ní ìhà ìlà-oòrùn: ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu.
19
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ó lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
20
Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri.
21
Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba (32,200).
22
Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni.
23
Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400).
24
Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
Settings