Skip to content
Numeri 15:12-16

Numeri 15:12-16

12
Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, iyekíye tí ẹ̀yin ìbá à pèsè.
13
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín ni kí ó máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí ó bá mú ọrẹ àfinásun gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn wá fún Olúwa.
14
Bí àlejò kan bá ń gbé láàrín yín ní gbogbo ìran yín, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ mú ọrẹ àfinásun bí òórùn dídùn wá fún Olúwa, gbogbo bí ẹ bá ṣe ń ṣe náà ni kí ó ṣe.
15
Gbogbo ìjọ ènìyàn gbọdọ̀ ní òfin kan náà fún ọmọ bíbí ilẹ̀ yín àti fún àwọn àlejò tó ń gbé láàrín yín, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Ẹ̀yin àti àlejò tó ń gbé láàrín yín sì jẹ́ bákan náà níwájú Olúwa.
16
Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options