Numeri 14:40-45
40
Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”
41
Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere!
42
Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín.
43
Nítorí pé àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń bẹ níwájú yín, ẹ̀yin yóò sì ti ipa idà ṣubú. Nítorí pé, ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.”
44
Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láìjẹ́ pé àpótí ẹ̀rí Olúwa tàbí Mose kúrò nínú ibùdó.
45
Àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Horma.
Settings