Nehemiah 6:5-9
5
Ní ìgbà karùn-ún, Sanballati rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú àpò ìwé wà ní ọwọ́ rẹ̀
6
tí a kọ sínú un rẹ̀ pé, “A ròyìn rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, Geṣemu sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé ìwọ àti àwọn Júù ń gbèrò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbèrò láti di ọba wọn
7
àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jerusalẹmu: ‘Ọba kan wà ní Juda!’ Nísinsin yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.”
8
Mo dá èsì yìí padà sí i pé, “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.”
9
Gbogbo wọn múra láti dẹ́rùbà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní parí rẹ̀.” Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsin yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”
Settings