Nehemiah 2:12-15
12
Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.
13
Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.
14
Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;
15
bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.
Settings