Matiu 9:20
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 20 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
17
Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”
18
Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.”
19
Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
20
Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀.
21
Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”
22
Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.
23
Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo.
Settings