Skip to content
Matiu 21:41-43

Matiu 21:41-43

41
Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”
42
Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú Ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?
43
“Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options