Matiu 19:1-7
1
Lẹ́yìn tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Galili. Ó sì yípo padà sí Judea, ó gba ìhà kejì odò Jordani.
2
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀.
3
Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?”
4
Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’
5
Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’
6
Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”
7
Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?”
Settings