Skip to content
Matiu 15:21-30

Matiu 15:21-30

21
Jesu sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tire àti Sidoni.
22
Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”
23
Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”
24
Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.”
25
Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”
26
Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
27
Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”
28
Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.
29
Jesu ti ibẹ̀ lọ sí Òkun Galili. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀.
30
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúnkùn ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Òun sì mú gbogbo wọn láradá.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options