Matiu 11:9-11
9
Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.”
10
Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi síwájú rẹ, ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
11
Lóòótọ́ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Johanu onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀jù ú lọ.
Settings