Marku 8:1-10
1
Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
2
Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ.
3
Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”
4
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”
5
Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?” Wọ́n fèsì pé, “Ìṣù àkàrà méje.”
6
Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.
7
Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà.
8
Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún.
9
Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ.
10
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta.
Settings