Marku 13:5
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 5 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
2
Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
3
Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé,
4
“Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹmpili náà? Kí ni yóò sì jẹ́ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”
5
Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín.
6
Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ.
7
Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.
8
Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jì ní ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.
Settings