Skip to content
Luku 24:38-47

Luku 24:38-47

38
Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín?
39
Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”
40
Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.
41
Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhìn-ín yìí?”
42
Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.
43
Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.
44
Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé, a ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”
45
Nígbà náà ni ó ṣí wọn ní iyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.
46
Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú,
47
àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options