Luku 22:55-62
55
Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn.
56
Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”
57
Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”
58
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.” Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”
59
Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”
60
Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ!
61
Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.”
62
Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
Settings