- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Ìmú Jésù
Luku 22:47-53
Ìmú Jésù
47
Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
48
Jesu sì wí fún un pé, “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ Ènìyàn hàn?”
49
Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?”
50
Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.
51
Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn.
52
Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá?
53
Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi, ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.”
Kẹ́kọ̀ọ́ ẹsẹ wọ̀nyí
Àlàyé lórí gbogbo ẹsẹ wọ̀nyí, kì í ṣe ẹsẹ kan ṣoṣo
- Ta ni
- Níbo
- Ìgbà wo
- About
Ibi mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ èyí
Johanu 18:11
Nítorí náà Jesu wí fún Peteru pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ, ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”láti ẹsẹ 47Johanu 18:10
Nígbà náà ni Simoni Peteru ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà a máa jẹ́ Makọọsi.láti ẹsẹ 50Luku 22:4
Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́.láti ẹsẹ 522 Samuẹli 20:9
Joabu sì bi Amasa léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” Joabu sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Amasa ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.láti ẹsẹ 482 Samuẹli 20:10
Ṣùgbọ́n Amasa kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Joabu, bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́, Amasa sì kú. Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ Bikri.láti ẹsẹ 48Marku 14:44
Judasi tí fi àmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jesu, ẹ mú un.”láti ẹsẹ 48Marku 14:46
Wọ́n sì mú Jesu.láti ẹsẹ 48Òwe 27:6
Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.láti ẹsẹ 48Marku 14:47
Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró fa idà rẹ̀ yọ, ó fi ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.láti ẹsẹ 50Luku 22:38
Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!” Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”láti ẹsẹ 492 Kọrinti 10:4
Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀.láti ẹsẹ 50Matiu 26:51
Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì sá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.láti ẹsẹ 50



Àkọsílẹ̀ Ẹ̀kọ́
Settings