Lefitiku 8:25-29
25
Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.
26
Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.
27
Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.
28
Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa.
29
Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Settings