Lefitiku 14:10-32
10
“Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n lógù òróró kan.
11
Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́, yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
12
“Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì.
13
Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
14
Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.
15
Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú lógù òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.
16
Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje.
17
Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀mọ́, lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi.
18
Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.
19
“Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun.
20
Kí àlùfáà kí ó sì rú ẹbọ sísun, àti ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà kí ó sì ṣe ètùtù fún un, òun yóò sì di mímọ́.
21
“Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró
22
àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.
23
“Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa.
24
Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì.
25
Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún.
26
Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.
27
Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa.
28
Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí.
29
Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún, láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú Olúwa.
30
Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ.
31
Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.”
32
Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.
Settings