Lefitiku 10:16-20
16
Nígbà tí Mose wádìí nípa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì rí i pé wọ́n ti sun ún, ó bínú sí Eleasari àti Itamari, àwọn ọmọ Aaroni yòókù, ó sì béèrè pé,
17
“Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbègbè ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú Olúwa.
18
Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí Ibi Mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbègbè Ibi Mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ.”
19
Aaroni sì dá Mose lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún ṣẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?”
20
Nígbà tí Mose gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀.
Settings