Ẹkún Jeremiah 5:1-10
1
Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
2
Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.
3
Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.
4
A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.
5
Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
6
Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
7
Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8
Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9
Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
10
Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
Settings