Ẹkún Jeremiah 4:11-16
11
Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.
12
Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jerusalẹmu.
13
Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrín rẹ̀.
14
Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú. Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.
15
“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”
16
Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà.
Settings