Ẹkún Jeremiah 1:1-4
1
Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan, nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn! Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó wà ní ipò opó, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú ni ó padà di ẹrú.
2
Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀ wọ́n ti di alátakò rẹ̀.
3
Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Juda lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi. Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́ ibi tí kò ti le sá àsálà.
4
Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn, àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú, òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.
Settings