Ẹkún Jeremiah 1:8-11
8
Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò.
9
Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì ṣí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, Olúwa, nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”
10
Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.
11
Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ láti mú wọn wà láààyè. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
Settings