Ẹkún Jeremiah 1:12-17
12
“Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá. Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.
13
“Ó rán iná láti òkè sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi. Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi, ó sì yí mi padà. Ó ti pa mí lára mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.
14
“Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà; ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀. Wọ́n ti yí ọrùn mi ká Olúwa sì ti dín agbára mi kù. Ó sì ti fi mí lé àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.
15
“Olúwa kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run. Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.
16
“Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún tí omijé sì ń dà lójú mi. Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi, kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà. Àwọn ọmọ mi di aláìní nítorí ọ̀tá ti borí.”
17
Sioni na ọwọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un Jerusalẹmu ti di ohun aláìmọ́ láàrín wọn.
Settings