Onidajọ 6:20-27
20
Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀.
21
Angẹli Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́.
22
Nígbà tí Gideoni sì ti mọ̀ dájúdájú pé angẹli Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Mo ti rí angẹli Olúwa ní ojúkorojú!”
23
Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kùú.”
24
Báyìí ni Gideoni mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní Ofira ti Abieseri títí di òní.
25
Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀.
26
Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
27
Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.
Settings