Onidajọ 6:11-21
11
Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù Ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani.
12
Nígbà tí angẹli Olúwa fi ara han Gideoni, ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.”
13
Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”
14
Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.”
15
Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba Israẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.”
16
Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Midiani láì ku ẹnìkankan.”
17
Gideoni sì dáhùn pé, nísinsin yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní àmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀.
18
Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ. Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.”
19
Gideoni sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì sè é, ó sì mú ìyẹ̀fun efa kan, ó fi ṣe àkàrà aláìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n, ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ angẹli náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù.
20
Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀.
21
Angẹli Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́.
Settings