Onidajọ 13:5-9
5
nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.”
6
Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.
7
Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ”
8
Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”
9
Ọlọ́run fetí sí ohùn Manoa, angẹli Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Manoa kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Settings