Joṣua 21:9-26
9
Láti ara ẹ̀yà Juda àti ẹ̀yà Simeoni ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí,
10
(ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
11
Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.)
12
Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbègbè ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kalebu ọmọ Jefunne gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.
13
Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ní Hebroni (ọ̀kan nínú ìlú ààbò fún àwọn apànìyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Libina,
14
Jattiri, Eṣitemoa,
15
Holoni àti Debiri,
16
Aini, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn-án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí.
17
Láti ara ẹ̀yà Benjamini ni wọ́n ti fún wọn ní: Gibeoni, Geba,
18
Anatoti àti Almoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.
19
Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Aaroni jẹ́ mẹ́tàlá pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn.
20
Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu.
21
Ní ilẹ̀ òkè Efraimu wọ́n fún wọn ní: Ṣekemu (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Geseri,
22
Kibasaimu àti Beti-Horoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
23
Láti ara ẹ̀yà Dani ni wọ́n ti fún wọn ní: Elteke, Gibetoni,
24
Aijaloni àti Gati-Rimoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
25
Láti ara ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún wọn ní: Taanaki àti Gati-Rimoni pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì.
26
Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kohati.
Settings