Skip to content
Joẹli 3:9-16

Joẹli 3:9-16

9
Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí; ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára. Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun.
10
Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.”
11
Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.
12
“Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
13
Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀, nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”
14
Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìpinnu! Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́.
15
Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
16
Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options