Jobu 40:6-13
6
Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,
7
“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
8
“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.
9
Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
10
Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
11
Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde; kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
12
Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀ kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13
Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.
Settings