Jobu 24:18-25
18
“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.
20
Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀; a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́; bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi.
21
Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó.
22
Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára, bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.
23
Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un, àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
24
A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ; a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, a sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.
25
“Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”
Settings