Jobu 17:6-10
6
“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
7
Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
8
Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9
Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
10
“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí; èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
Settings