Jobu 17:11-16
11
Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá, àní ìrò ọkàn mi.
12
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13
Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi; mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.
14
Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
15
ìrètí mi ha dà nísinsin yìí? Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
16
Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”
Settings