Skip to content
Jeremiah 52:17-23

Jeremiah 52:17-23

17
Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli.
18
Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ.
19
Balógun ìṣọ́ náà kó àwokòtò wọ̀n-ọn-nì, ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti ago wáìnì wọ̀n-ọn-nì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.
20
Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ.
21
Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú.
22
Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra.
23
Pomegiranate mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options