Skip to content
Jeremiah 51:1-10

Jeremiah 51:1-10

1
Ohùn ti Olúwa wí nìyìí: “Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai,
2
Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo; wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.
3
Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀, jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀. Má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí; pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
4
Gbogbo wọn ni yóò ṣubú ní Babeli, tí wọn yóò sì fi ara pa yánnayànna ní òpópónà.
5
Nítorí pé Juda àti Israẹli ni Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun, kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.
6
“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí; yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
7
Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa; ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí. Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.
8
Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́. Ẹ hu fun un! Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ, bóyá yóò le wo ọ́ sàn.
9
“ ‘À bá ti wo Babeli sàn, ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀, kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè, ó ga àní títí dé òfúrufú.’
10
“ ‘Olúwa ti dá wa láre, wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa ti ṣe.’
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options