Jeremiah 5:4-17
4
Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
5
Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ, n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.” Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́, wọ́n sì ti já ìdè.
6
Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.
7
“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.
8
Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.
9
Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?
10
“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.
11
Ilé Israẹli àti ilé Juda ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,” ni Olúwa wí.
12
Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.
13
Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”
14
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.
15
Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.
16
Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.
17
Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings