Skip to content
Jeremiah 46:1-9

Jeremiah 46:1-9

1
Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè.
2
Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
3
“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!
4
Ẹ di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún. Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àṣíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
5
Kí ni nǹkan tí mo tún rí? Wọ́n bẹ̀rù, wọ́n sì ń padà sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun. Wọ́n sá, wọn kò sì bojú wẹ̀yìn, ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,” ni Olúwa wí.
6
“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ, tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà. Ní àríwá ní ibi odò Eufurate wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
7
“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti, tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?
8
Ejibiti dìde bí odò náà, bí omi odò tí ń ru. Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’ Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
9
Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin, ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́. Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú, àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú; àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options