Jeremiah 44:25-27
25
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’ “Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.
26
Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí, ‘pé kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra, “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.”
27
Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán.
Settings