Skip to content
Jeremiah 36:10-26

Jeremiah 36:10-26

10
Láti inú yàrá Gemariah ọmọ Ṣafani akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Baruku sì ka ọ̀rọ̀ Jeremiah láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.
11
Nígbà tí Mikaiah ọmọ Gemariah ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà;
12
Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Eliṣama akọ̀wé, Delaiah ọmọ Ṣemaiah, Elnatani ọmọ Akbori, Gemariah ọmọ Ṣafani àti Sedekiah ọmọ Hananiah àti gbogbo àwọn ìjòyè.
13
Lẹ́yìn tí Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Baruku kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn.
14
Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jehudu ọmọ Netaniah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Kuṣi sí Baruku wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Baruku ọmọ Neriah wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀.
15
Wọ́n sì wí fún pé, “Jókòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!” Nígbà náà ni Baruku sì kà á ní etí wọn.
16
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Baruku pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.”
17
Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?”
18
Baruku sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”
19
Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”
20
Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíká náà pamọ́ sí iyàrá Eliṣama akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba.
21
Ọba sì rán Jehudu láti lọ mú ìwé kíká náà wá, Jehudu sì mu jáde láti inú iyàrá Eliṣama akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti ọba.
22
Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsànán, ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná ààrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀.
23
Nígbà tí Jehudu ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé kíká náà fi jóná tán.
24
Síbẹ̀, ọba àti gbogbo àwọn ẹ̀mẹwà rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá.
25
Elnatani, Delaiah àti Gemariah sì bẹ ọba kí ó má ṣe fi ìwé kíká náà jóná, ṣùgbọ́n ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn.
26
Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options