Fò sí àkóónú
Jeremiah 31:35-40

Jeremiah 31:35-40

35
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
36
“Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.”
37
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀, ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,” ni Olúwa wí.
38
“Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè.
39
Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Garebu yóò sì lọ sí Goa.
40
Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì Kidironi ní ìhà ìlà-oòrùn títí dé igun ẹnu ibodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options