Skip to content
Jeremiah 25:30-33

Jeremiah 25:30-33

30
“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí.
31
Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ” ni Olúwa wí.
32
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn; ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”
33
Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options