Jeremiah 17:22-27
22
Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.”
23
Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.
24
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà.
25
Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.
26
Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa.
27
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”
Settings